• ÌKÉDE KÁRÍAYÉ FÚN È̟TÓ̟ O̟MO̟NÌYÀN

  • Universal Declaration of Human Rights

Ò̟RÒ̟ ÀKÓ̟SO̟ .      Preamble.

Bí ó ti jé̟ pé s̟ís̟e àkíyèsí iyì tó jé̟ àbímó̟ fún è̟dá àti ìdó̟gba è̟tó̟ t̟̟̟̟í kò s̟eé mú kúrò tí è̟dá kò̟ò̟kan ní, ni òkúta ìpìlè̟ fún òmìnira, ìdájó̟ òdodo àti àlàáfíà lágbàáyé,

Whereas recognition of the inherent dignity and of the equal and inalienable rights of all members of the human family is the foundation of freedom, justice and peace in the world,

Bí ó ti jé̟ pé àìka àwo̟n è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn sí àti ìké̟gàn àwo̟n è̟tó̟ wò̟nyí ti s̟e okùnfà fún àwo̟n ìwà búburú kan, tó mú è̟rí-o̟kàn è̟dá gbo̟gbé̟, tó sì jé̟ pé ìbè̟rè̟ ìgbé ayé titun, nínú èyí tí àwo̟n ènìyàn yóò ti ní òmìnira òrò̟ síso̟ àti òmìnira láti gba ohun tó bá wù wó̟n gbó̟, òmìnira ló̟wó̟ è̟rù àti òmìnira ló̟wó̟ àìní, ni a ti kà sí àníyàn tó ga jù lo̟ ló̟kàn àwo̟n o̟mo̟-èniyàn,

Whereas disregard and contempt for human rights have resulted in barbarous acts which have outraged the conscience of mankind, and the advent of a world in which human beings shall enjoy freedom of speech and belief and freedom from fear and want has been proclaimed as the highest aspiration of the common people,

Bí ó ti jé̟̟ pé ó s̟e pàtàkì kí a dáàbò bo àwo̟n è̟tó o̟mo̟nìyàn lábé̟ òfin, bí a kò bá fé̟ ti àwo̟n ènìyàn láti ko̟jú ìjà sí ìjo̟ba ipá àti ti amúnisìn, nígbà tí kò bá sí ò̟nà àbáyo̟ mìíràn fún wo̟n láti bèèrè è̟tó̟ wo̟n,

Whereas it is essential, if man is not to be compelled to have recourse, as a last resort, to rebellion against tyranny and oppression, that human rights should be protected by the rule of law,

Bí ó ti jé̟ pé ó s̟e pàtàkì kí ìdàgbàsókè ìbás̟epò̟ ti ò̟ré̟-sí-ò̟ré̟ wà láàrin àwo̟n orílè̟-èdè,

Whereas it is essential to promote the development of friendly relations between nations,

Bí ó ti jé̟ pé gbogbo o̟mo̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé tún ti te̟nu mó̟ ìpinnu tí wó̟n ti s̟e té̟lè̟ nínú ìwé àdéhùn wo̟n, pé àwo̟n ní ìgbàgbó̟ nínú è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí, ìgbàgbó̟ nínú iyì àti è̟ye̟ è̟dá ènìyàn, àti ìgbàgbó̟ nínú ìdó̟gba è̟tó̟ láàrin o̟kùnrin àti obìnrin, tó sì jé̟ pé wó̟n tún ti pinnu láti s̟e ìgbéláruge̟ ìtè̟síwájú àwùjo̟ nínú èyí tí òmìnira ètò ìgbé-ayé rere è̟dá ti lè gbòòrò sí i,

Whereas the peoples of the United Nations have in the Charter reaffirmed their faith in fundamental human rights, in the dignity and worth of the human person and in the equal rights of men and women and have determined to promote social progress and better standards of life in larger freedom,

Bí ó ti jé̟ pé àwo̟n o̟mo̟ e̟gbé̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé ti jé̟jè̟é̟ láti fo̟wó̟s̟owó̟ pò̟ pè̟lú Àjo̟ náà, kí won lè jo̟ s̟e às̟eyege nípa àmús̟e̟ àwo̟n è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn àti òmìnira è̟dá tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí àti láti rí i pé à ń bò̟wò̟ fún àwo̟n è̟tó̟ náà káríayé,

Whereas Member States have pledged themselves to achieve, in cooperation with the United Nations, the promotion of universal respect for and observance of human rights and fundamental freedoms,

Bí ó ti jé̟ pé àfi tí àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí bá yé ènìyàn nìkan ni a fi lè ní àmús̟e̟ è̟jé̟ yìí ní kíkún,

Whereas a common understanding of these rights and freedoms is of the greatest importance for the full realization of this pledge,

Ní báyìí,

Now, therefore,

Àpapò̟̟ ìgbìmò̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé

The General Assembly,

s̟e ìkéde káríayé ti è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn, gé̟gé̟ bí ohun àfojúsùn tí gbogbo è̟dá àti orílè̟-èdè jo̟ ń lépa ló̟nà tó jé̟ pé e̟nì kò̟ò̟kan àti è̟ka kò̟ò̟kan láwùjo̟ yóò fi ìkéde yìí só̟kàn, tí wo̟n yóò sì rí i pé àwo̟n lo ètò-ìkó̟ni àti ètò-è̟kó̟ láti s̟e ìgbéláruge̟ ìbò̟wò̟ fún è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí. Bákan náà, a gbo̟dò̟ rí àwo̟n ìgbésè̟ tí ó lè mú ìlo̟síwájú bá orílè̟-èdè kan s̟os̟o tàbí àwo̟n orílè̟-èdè sí ara wo̟n, kí a sì rí i pé a fi ò̟wò̟ tó jo̟jú wo̟ àwo̟n òfin wò̟nyí, kí àmúlò wo̟n sì jé̟ káríayé láàrin àwo̟n ènìyàn orílè̟-èdè tó jé̟ o̟mo̟ Àjo̟-ìsò̟kan àgbáyé fúnra wo̟n àti láàrin àwo̟n ènìyàn orílè̟-èdè mìíràn tó wà lábé̟ às̟e̟ wo̟n.

Proclaims this Universal Declaration of Human Rights as a common standard of achievement for all peoples and all nations, to the end that every individual and every organ of society, keeping this Declaration constantly in mind, shall strive by teaching and education to promote respect for these rights and freedoms and by progressive measures, national and international, to secure their universal and effective recognition and observance, both among the peoples of Member States themselves and among the peoples of territories under their jurisdiction.

Abala kìíní.      Article 1.

Gbogbo ènìyàn ni a bí ní òmìnira; iyì àti è̟tó̟ kò̟ò̟kan sì dó̟gba. Wó̟n ní è̟bùn ti làákàyè àti ti è̟rí-o̟kàn, ó sì ye̟ kí wo̟n ó máa hùwà sí ara wo̟n gé̟gé̟ bí o̟mo̟ ìyá.

All human beings are born free and equal in dignity and rights. They are endowed with reason and conscience and should act towards one another in a spirit of brotherhood.

Abala kejì.      Article 2.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní àǹfàní sí gbogbo è̟tó̟ àti òmìnira tí a ti gbé kalè̟ nínú ìkéde yìí láìfi ti ò̟rò̟ ìyàtò̟ è̟yà kankan s̟e; ìyàtò̟ bí i ti è̟yà ènìyàn, àwò̟̟̟, ako̟-n̅-bábo, èdè, è̟sìn, ètò ìs̟èlú tàbí ìyàtò̟ nípa èrò e̟ni, orílè̟-èdè e̟ni, orírun e̟ni, ohun ìní e̟ni, ìbí e̟ni tàbí ìyàtò̟̟ mìíràn yòówù kó jé̟.

Everyone is entitled to all the rights and freedoms set forth in this Declaration, without distinction of any kind, such as race, colour, sex, language, religion, political or other opinion, national or social origin, property, birth or other status.

Síwájú sí i, a kò gbo̟dò̟ ya e̟nìké̟ni só̟tò̟ nítorí irú ìjo̟ba orílè̟-èdè rè̟ ní àwùjo̟ àwo̟n orílè̟-èdè tàbí nítorí ètò-ìs̟èlú tàbí ètò-ìdájó̟ orílè̟-èdè rè̟; orílè̟-èdè náà ìbáà wà ní òmìnira tàbí kí ó wà lábé̟ ìs̟àkóso ilè̟ mìíràn, wo̟n ìbáà má dàá ìjo̟ba ara wo̟n s̟e tàbí kí wó̟n wà lábé̟ ìkáni-lápá-kò yòówù tí ìbáà fé̟ dí òmìnira wo̟n ló̟wó̟ gé̟gé̟ bí orílè̟-èdè.

Furthermore, no distinction shall be made on the basis of the political, jurisdictional or international status of the country or territory to which a person belongs, whether it be independent, trust, non-self-governing or under any other limitation of sovereignty.

Abala ke̟ta.      Article 3.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti wà láàyè, è̟tó̟ sí òmìnira àti è̟tó̟ sí ààbò ara rè̟.

Everyone has the right to life, liberty and security of person.

Abala ke̟rin.      Article 4.

A kò gbo̟dò̟ mú e̟niké̟ni ní e̟rú tàbí kí a mú un sìn; e̟rú níní àti ò wò e̟rú ni a gbo̟dò̟ fi òfin dè ní gbogbo ò̟nà.

No one shall be held in slavery or servitude; slavery and the slave trade shall be prohibited in all their forms.

Abala karùn-ún.      Article 5.

A kò gbo̟dò̟ dá e̟nì ké̟ni lóró tàbí kí a lò ó ní ìlò ìkà tí kò ye̟ o̟mo̟ ènìyàn tàbí ìlò tó lè tàbùkù è̟dá ènìyàn.

No one shall be subjected to torture or to cruel, inhuman or degrading treatment or punishment.

Abala ke̟fà.      Article 6.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ pé kí a kà á sí gé̟gé̟ bí ènìyàn lábé̟ òfin ní ibi gbogbo.

Everyone has the right to recognition everywhere as a person before the law.

Abala keje.      Article 7.

Gbogbo ènìyàn ló dó̟gba lábé̟ òfin. Wó̟n sì ní è̟tó̟ sí àà bò lábé̟ òfin láìsí ìyàsó̟tò̟ kankan. Gbogbo ènìyàn ló ní è̟tó̟ sí ààbò tó dó̟gba kúrò ló̟wó̟ ìyàsó̟tò̟ yòówù tí ìbáà lòdì sí ìkéde yìí àti è̟tó̟ kúrò ló̟wó̟ gbogbo ohun tó bá lè ti ènìyàn láti s̟e irú ìyàsó̟tò̟ bé̟è̟.

All are equal before the law and are entitled without any discrimination to equal protection of the law. All are entitled to equal protection against any discrimination in violation of this Declaration and against any incitement to such discrimination.

Abala ke̟jo̟.      Article 8.

E̟nì kò̟ò̟kan lórílè̟-èdè, ló ní è̟tó̟ sí àtúns̟e tó jo̟jú ní ilé-e̟jó̟ fún ìwà tó lòdì sí è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn, tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí gé̟gé̟ bó s̟e wà lábé̟ òfin àti bí òfin-ìpìlè̟ s̟e là á sílè̟.

Everyone has the right to an effective remedy by the competent national tribunals for acts violating the fundamental rights granted him by the constitution or by law.

Abala ke̟sàn-án.      Article 9.

A kò gbo̟dò̟ s̟àdédé fi òfin mú ènìyàn tàbí kí a kàn gbé ènìyàn tì mó̟lé, tàbí kí a lé ènìyàn jáde ní ìlú láìnídìí.

No one shall be subjected to arbitrary arrest, detention or exile.

Abala ke̟wàá.      Article 10.

E̟nì kò̟ò̟kan tí a bá fi è̟sùn kàn ló ní è̟tó̟ tó dó̟gba, tó sì kún, láti s̟àlàyé ara rè̟ ní gban̅gba, níwájú ilé-e̟jó̟ tí kò s̟ègbè, kí wo̟n lè s̟e ìpinnu lórí è̟tó̟ àti ojús̟e rè̟ nípa irú è̟sùn ò̟ràn dídá tí a fi kàn án.

Everyone is entitled in full equality to a fair and public hearing by an independent and impartial tribunal, in the determination of his rights and obligations and of any criminal charge against him.

Abala ko̟kànlá.      Article 11.

E̟nìké̟ni tí a fi è̟sùn kàn ni a gbo̟dò̟ gbà wí pé ó jàrè títí è̟bi rè̟ yóò fi hàn lábé̟ òfin nípasè̟ ìdájó̟ tí a s̟e ní gban|gba nínú èyí tí e̟ni tí a fi è̟sùn kàn yóò ti ní gbogbo ohun tí ó nílò láti fi s̟e àwíjàre ara rè̟.

Everyone charged with a penal offence has the right to be presumed innocent until proved guilty according to law in a public trial at which he has had all the guarantees necessary for his defence.

A kò gbo̟dò̟ dá è̟bi è̟s̟è̟ fún e̟nìké̟ni fún pé ó hu ìwà kan tàbí pé ó s̟e àwo̟n àfojúfò kàn nígbà tó jé̟ pé lásìkò tí èyí s̟e̟lè̟, irú ìwà bé̟è̟ tàbí irú àfojúfò bé̟è̟ kò lòdì sí òfin orílè̟-èdè e̟ni náà tàbí òfin àwo̟n orílè̟-èdè àgbáyé mìíràn. Bákan náà, ìje̟níyà tí a lè fún e̟ni tó dé̟s̟è̟ kò gbo̟dò̟ ju èyí tó wà ní ìmúlò ní àsìkò tí e̟ni náà dá è̟s̟è̟ rè̟.

No one shall be held guilty of any penal offence on account of any act or omission which did not constitute a penal offence, under national or international law, at the time when it was committed. Nor shall a heavier penalty be imposed than the one that was applicable at the time the penal offence was committed.

Abala kejìlá.      Article 12.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ pé kí a má s̟àdédé s̟e àyo̟júràn sí ò̟rò̟ ìgbésí ayé rè̟, tàbí sí ò̟rò̟e̟bí rè̟ tàbí sí ò̟rò̟ ìdílé rè̟ tàbí ìwé tí a ko̟ sí i; a kò sì gbo̟dò̟ ba iyì àti orúko̟ rè̟ jé̟. E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ààbò lábé̟ òfin kúrò ló̟wó̟ irú àyo̟júràn tàbí ìbanijé̟ bé̟è̟.

No one shall be subjected to arbitrary interference with his privacy, family, home or correspondence, nor to attacks upon his honour and reputation. Everyone has the right to the protection of the law against such interference or attacks.

Abala ke̟tàlá.      Article 13.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti rìn káàkiri ní òmìnira kí ó sì fi ibi tó bá wù ú s̟e ìbùgbé láàrin orílè̟-èdè rè̟.

Everyone has the right to freedom of movement and residence within the borders of each State.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti kúrò lórílè̟-èdè yòówù kó jé̟, tó fi mó̟ orílè̟-èdè tirè̟, kí ó sì tún padà sí orílè̟-èdè tirè̟ nígbà tó bá wù ú.

Everyone has the right to leave any country, including his own, and to return to his country.

Abala ke̟rìnlá.      Article 14.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti wá ààbò àti láti je̟ àn fàní ààbò yìí ní orílè̟-èdè mìíràn nígbà tí a bá ń s̟e inúnibíni sí i.

Everyone has the right to seek and to enjoy in other countries asylum from persecution.

A kò lè lo è̟tó̟ yìí fún e̟ni tí a bá pè lé̟jó̟ tó dájú nítorí e̟ s̟̟è̟ tí kò je̟ mó̟ ò̟rò̟ ìs̟èlú tàbí ohun mìíràn tí ó s̟e tí kò bá ète àti ìgbékalè̟ Ajo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé mu.

This right may not be invoked in the case of prosecutions genuinely arising from non-political crimes or from acts contrary to the purposes and principles of the United Nations.

Abala ke̟è̟é̟dógún.      Article 15.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti jé̟ o̟mo̟ orílè̟-èdè kan.

Everyone has the right to a nationality.

A kò lè s̟àdédé gba è̟tó̟ jíjé̟ o̟mo̟ orílè̟-èdè e̟ni ló̟wó̟ e̟nìké̟ni láìnídìí tàbí kí a kò̟ fún e̟nìké̟ni láti yàn láti jé̟ o̟mo̟ orílè̟-èdè mìíràn.

No one shall be arbitrarily deprived of his nationality nor denied the right to change his nationality.

Abala ke̟rìndínlógún.      Article 16.

To̟kùnrin tobìnrin tó bá ti bàlágà ló ní è̟tó̟ láti fé̟ ara wo̟n, kí wó̟n sì dá e̟bí ti wo̟n sílè̟ láìsí ìkanilápá-kò kankan nípa è̟yà wo̟n, tàbí orílè̟-èdè wo̟n tàbí è̟sìn wo̟n. E̟tó̟ wo̟n dó̟gba nínú ìgbeyàwó ìbáà jé̟ nígbà tí wo̟n wà papò̟ tàbí lé̟yìn tí wó̟n bá ko̟ ara wo̟n.

Men and women of full age, without any limitation due to race, nationality or religion, have the right to marry and to found a family. They are entitled to equal rights as to marriage, during marriage and at its dissolution.

A kò gbo̟dò̟ s̟e ìgbeyàwó kan láìjé̟ pé àwo̟n tí ó fé̟ fé̟ ara wo̟n ní òmìnira àto̟kànwá tó péye láti yàn fúnra wo̟n.

Marriage shall be entered into only with the free and full consent of the intending spouses.

E̟bí jé̟ ìpìlè̟ pàtàkì àdánidá ní àwùjo̟, ó sì ní è̟tó̟ pé kí àwùjo̟ àti orílè̟-èdè ó dáàbò bò ó.

The family is the natural and fundamental group unit of society and is entitled to protection by society and the State.

Abala ke̟tàdínlógún.      Article 17.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti dá ohun ìní ara rè̟ ní tàbí láti ní in papò̟ pè̟lú àwo̟n mìíràn.

Everyone has the right to own property alone as well as in association with others.

A kò lè s̟àdédé gba ohun ìní e̟nì kan ló̟wó̟ rè̟ láìnídìí.

No one shall be arbitrarily deprived of his property.

Abala kejìdínlógún.      Article 18.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟̟tó̟ sí òmìnira èrò, òmìnira è̟rí-o̟kàn àti òmìnira e̟ sìn. E̟tó̟ yìí sì gbani láàyè láti pààrò̟ e̟ sìn tàbí ìgbàgbó̟ e̟ni. Ó sì fún e̟yo̟ e̟nì kan tàbí àkójo̟pò̟ ènìyàn láàyè láti s̟e è̟sìn wo̟n àti ìgbàgbó̟ wo̟n bó s̟e je̟ mó̟ ti ìkó̟ni, ìs̟esí, ìjó̟sìn àti ìmús̟e ohun tí wó̟n gbàgbó̟ yálà ní ìkò̟kò̟ tàbí ní gban̅gba.

Everyone has the right to freedom of thought, conscience and religion; this right includes freedom to change his religion or belief, and freedom, either alone or in community with others and in public or private, to manifest his religion or belief in teaching, practice, worship and observance.

Abala ko̟kàndínlógún.      Article 19.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí òmì nira láti ní ìmò̟ràn tí ó wù ú, kí ó sì so̟ irú ìmò̟ràn bé̟è̟ jáde; è̟tó̟yìí gbani láàyè láti ní ìmò̟ràn yòówù láìsí àtakò láti ò̟dò̟ e̟nìké̟ni láti wádìí ò̟rò̟, láti gba ìmò̟ràn ló̟dò̟ e̟lòmíràn tàbí láti gbani níyànjú ló̟nàkó̟nà láìka ààlà orílè̟-èdè kankan kún.

Everyone has the right to freedom of opinion and expression; this right includes freedom to hold opinions without interference and to seek, receive and impart information and ideas through any media and regardless of frontiers.

Abala ogún.      Article 20.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí òmìnira láti pé jo̟ pò̟ àti láti dara pò̟ mó̟ àwo̟n mìíràn ní àlàáfíà.

Everyone has the right to freedom of peaceful assembly and association.

A kò lè fi ipá mú e̟nìké̟ni dara pò̟ mó̟ e̟gbé̟ kankan.

No one may be compelled to belong to an association.

Abala ko̟kànlélógún.      Article 21.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟̟tó̟ láti kópa nínú ìs̟àkóso orílè̟-èdè rè̟, yálà fúnra rè̟ tàbí nípasè̟ àwo̟n as̟ojú tí a kò fi ipá yàn.

Everyone has the right to take part in the government of his country, directly or through freely chosen representatives.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ tó dó̟gba láti s̟e is̟é̟ ìjo̟ba ní orílè̟-èdè rè̟.

Everyone has the right to equal access to public service in his country.

I fé̟ àwo̟n ènìyàn ìlú ni yóò jé̟ òkúta ìpìlè̟ fún à s̟e̟ ìjo̟ba; a ó máa fi ìfé̟ yìí hàn nípasè̟ ìbò tòótó̟ tí a ó máa dì láti ìgbà dé ìgbà, nínú èyí tí e̟nì kò̟ò̟kan yóò ní è̟tó̟ sí ìbò kan s̟os̟o tí a dì ní ìkò̟kò̟ tàbí nípasè̟ irú o̟ nà ìdìbò mìíràn tí ó bá irú ìdìbò bé̟è̟ mu.

The will of the people shall be the basis of the authority of government; this will shall be expressed in periodic and genuine elections which shall be by universal and equal suffrage and shall be held by secret vote or by equivalent free voting procedures.

Abala kejìlélógún.      Article 22.

E̟nì kò̟ò̟kan gé̟gé̟̟ bí è̟yà nínú àwùjo̟ ló ní è̟tó̟ sí ìdáàbò bò láti o̟wó̟ ìjo̟ba àti láti jé̟ àn fà ní àwo̟n è̟tó̟ tí ó bá o̟rò̟-ajé, ìwà láwùjo̟ àti às̟à àbínibí mu; àwo̟n è̟tó̟ tí ó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí fún iyì àti ìdàgbàsókè è̟dá ènìyàn, nípa akitiyan nínú orílè̟-èdè àti ìfo̟wó̟s̟owó̟ pò̟ láàrin àwo̟n orílè̟-èdè ní ìbámu pè̟lú ètò àti ohun àlùmó̟nì orílè̟-èdè kò̟ò̟kan.

Everyone, as a member of society, has the right to social security and is entitled to realization, through national effort and international co-operation and in accordance with the organization and resources of each State, of the economic, social and cultural rights indispensable for his dignity and the free development of his personality.

Abala ke̟tàlélógún.      Article 23.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti s̟is̟é̟, láti yan irú is̟é̟ tí ó wù ú, lábé̟ àdéhùn tí ó tó̟ tí ó sì tún ro̟rùn, kí ó sì ní ààbò kúrò ló̟wó̟ àìrís̟é̟ s̟e.

Everyone has the right to work, to free choice of employment, to just and favourable conditions of work and to protection against unemployment.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti gba iye owó tí ó dó̟gba fún irú is̟é̟ kan náà, láìsí ìyàsó̟tò̟ kankan.

Everyone, without any discrimination, has the right to equal pay for equal work.

E̟nì kò̟ò̟kan tí ó bá ń s̟isé̟ ní è̟tó̟ láti gba owó os̟ù tí ó tó̟ tí yóò sì tó fún òun àti e̟bí rè̟ láti gbé ayé tí ó bu iyì kún ènìyàn; a sì lè fi kún owó yìí nípasè̟ orís̟ìí àwo̟n ètò ìrànló̟wó̟ mìíràn nígbà tí ó bá ye.

Everyone who works has the right to just and favourable remuneration ensuring for himself and his family an existence worthy of human dignity, and supplemented, if necessary, by other means of social protection.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti dá e̟gbé̟ òs̟ìs̟é̟ sílè̟ àti láti dara pò̟ mó̟ irú e̟gbe̟; bé̟è̟ láti dáàbò bo àwo̟n ohun tí ó je̟ é̟ lógún.

Everyone has the right to form and to join trade unions for the protection of his interests.

Abala ke̟rìnlélógún.      Article 24.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ìsinmi àti fàájì pè̟lú àkókò tí kò pò̟ jù lé̟nu is̟é̟ àti àsìkò ìsinmi lé̟nu is̟é̟ láti ìgbà dé ìgbà tí a ó sanwó fún.

Everyone has the right to rest and leisure, including reasonable limitation of working hours and periodic holidays with pay.

Abala ke̟è̟é̟dó̟gbò̟n.      Article 25.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti gbé ìgbé ayé tó bójú mu nínú èyí tí òun àti e̟bí rè̟ yóò wà ní ìlera àti àlàáfíà, tí wo̟n yóò sì ní oúnje̟, as̟o̟, ilégbèé, àti àn fàní fún ìwòsàn àti gbogbo ohun tó lè mú è̟dá gbé ìgbé ayé rere. Bákan náà, e̟nì kò̟ò̟kan ló tún ní ààbò nígbà àìnís̟é̟ló̟wó̟, nígbà àìsà n, nígbà tó bá di aláàbò̟-ara, ní ipò opó, nígbà ogbó rè̟ tàbí ìgbà mìíràn tí ènìyàn kò ní ò̟nà láti rí oúnje̟ òò jó̟, tí eléyìí kì í sì í s̟e è̟bi olúwa rè̟.

Everyone has the right to a standard of living adequate for the health and well-being of himself and of his family, including food, clothing, housing and medical care and necessary social services, and the right to security in the event of unemployment, sickness, disability, widowhood, old age or other lack of livelihood in circumstances beyond his control.

A ní láti pèsè ìtó̟jú àti ìrànló̟wó̟ pàtàkì fún àwo̟n abiyamo̟ àti àwo̟n o̟mo̟dé. Gbogbo àwo̟n o̟mo̟dé yóò máa je̟ àwo̟n àn fàní ààbò kan náà nínú àwùjo̟ yálà àwo̟n òbí wo̟n fé̟ ara wo̟n ni tàbí wo̟n kò fé̟ ara wo̟n.

Motherhood and childhood are entitled to special care and assistance. All children, whether born in or out of wedlock, shall enjoy the same social protection.

Abala ke̟rìndínló̟gbò̟n.      Article 26.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti kó̟ è̟kó̟. Ó kéré tán, è̟kó̟ gbo̟dò̟ jé̟ ò̟fé̟ ní àwo̟n ilé-è̟kó̟ alákò̟ó̟bè̟rè̟. E̟kó̟ ní ilé-è̟kó̟ alákò̟ó̟bè̟rè̟ yìí sì gbo̟dò̟ jé̟ dandan. A gbo̟dò̟ pèsè è̟kó̟ is̟é̟-o̟wó̟, àti ti ìmò̟-è̟ro̟ fún àwo̟n ènìyàn lápapò̟. Àn fàní tó dó̟gba ní ilé-è̟kó̟ gíga gbo̟dò̟ wà ní àró̟wó̟tó gbogbo e̟ni tó bá tó̟ sí.

Everyone has the right to education. Education shall be free, at least in the elementary and fundamental stages. Elementary education shall be compulsory. Technical and professional education shall be made generally available and higher education shall be equally accessible to all on the basis of merit.

Ohun tí yóò jé̟ ète è̟kó̟ ni láti mú ìlo̟síwájú tó péye bá è̟dá ènìyàn, kí ó sì túbò̟ rí i pé àwo̟n ènìyàn bò̟wò̟ fún è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn àti àwo̟n òmìnira wo̟n, tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí. E tò è̟kó̟ gbo̟dò̟ lè rí i pé è̟mí; ìgbó̟ra-e̟ni-yé, ìbágbépò̟ àlàáfíà, àti ìfé̟ ò̟ré̟-sí-ò̟ré̟ wà láàrin orílè̟-èdè, láàrin è̟yà kan sí òmíràn àti láàrin e̟lé̟sìn kan sí òmíràn. E tò-è̟kó̟ sì gbo̟dò̟ kún àwo̟n akitiyan Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé ló̟wó̟ láti rí i pé àlàáfíà fìdí múlè̟.

Education shall be directed to the full development of the human personality and to the strengthening of respect for human rights and fundamental freedoms. It shall promote understanding, tolerance and friendship among all nations, racial or religious groups, and shall further the activities of the United Nations for the maintenance of peace.

Àwo̟n òbí ló ní è̟tó̟ tó ga jù lo̟ láti yan è̟kó̟ tí wó̟n bá fé̟ fún àwo̟n o̟mo̟ wo̟n.

Parents have a prior right to choose the kind of education that shall be given to their children.

Abala ke̟tàdínló̟gbò̟n.      Article 27.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láìjé̟ pé a fi ipá mú un láti kópa nínú àpapò̟ ìgbé ayé àwùjo̟ rè̟, kí ó je̟ ìgbádùn gbogbo ohun àmús̟e̟ wà ibè̟, kí ó sì kópa nínú ìdàgbàsókè ìmò̟ sáyé̟n sì àti àwo̟n àn fàní tó ń ti ibè̟ jáde.

Everyone has the right freely to participate in the cultural life of the community, to enjoy the arts and to share in scientific advancement and its benefits.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ààbò àn fàní ìmo̟yì àti ohun ìní tí ó je̟ yo̟ láti inú is̟é̟ yòówù tí ó bá s̟e ìbáà s̟e ìmò̟ sáyé̟n sì, ìwé kíko̟ tàbí is̟é̟ o̟nà.

Everyone has the right to the protection of the moral and material interests resulting from any scientific, literary or artistic production of which he is the author.

Abala kejìdínló̟gbò̟n.      Article 28.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ètò nínú àwùjo̟ rè̟ àti ní gbogbo àwùjo̟ àgbáyé níbi tí àwo̟n è̟tó̟ òmìnira tí a ti gbé kalè̟ nínú ìkéde yìí yóò ti jé̟ mímús̟e̟.

Everyone is entitled to a social and international order in which the rights and freedoms set forth in this Declaration can be fully realized.

Abala ko̟kàndínló̟gbò̟n.      Article 29.

E̟nì kò̟ò̟kan ló ní àwo̟n ojús̟e kan sí àwùjo̟, nípasè̟ èyí tí ó fi lè s̟eé s̟e fún e̟ni náà láti ní ìdàgbàsókè kíkún gé̟gé̟ bí è̟dá ènìyàn.

Everyone has duties to the community in which alone the free and full development of his personality is possible.

O fin yóò de e̟nì kò̟ò̟kan láti fi ò̟wò̟ àti ìmo̟yì tí ó tó̟ fún è̟tó̟ àti òmìnira àwo̟n e̟lòmíràn nígbà tí e̟ni náà bá ń lo àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira ara rè̟. E yí wà ní ìbámu pè̟lú ò̟nà tó ye̟, tó sì tó̟ láti fi báni lò nínú àwùjo̟ fún ire àti àlàáfíà àwùjo̟ náà nínú èyí tí ìjo̟ba yóò wà ló̟wó̟ gbogbo ènìyàn.

In the exercise of his rights and freedoms, everyone shall be subject only to such limitations as are determined by law solely for the purpose of securing due recognition and respect for the rights and freedoms of others and of meeting the just requirements of morality, public order and the general welfare in a democratic society.

A kò gbo̟dò̟ lo àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí rárá, ní ò̟nà yòówù kó jé̟, tó bá lòdì sí àwo̟n ète àti ìgbékalè̟ Ajo̟-àpapò̟ orílè̟-èdè agbáyé.

These rights and freedoms may in no case be exercised contrary to the purposes and principles of the United Nations.

Abala o̟gbò̟n.      Article 30.

A kò gbo̟dò̟ túmò̟ ohunkóhun nínú ìkéde yìí gé̟gé̟ bí ohun tí ó fún orílè̟-èdè kan tàbí àkójo̟pò̟ àwo̟n ènìyàn kan tàbí e̟nìké̟ni ní è̟tó̟ láti s̟e ohunkóhun tí yóò mú ìparun bá èyíkéyìí nínú àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira tí a kéde yìí.

Nothing in this Declaration may be interpreted as implying for any State, group or person any right to engage in any activity or to perform any act aimed at the destruction of any of the rights and freedoms set forth herein.

Support This Project

your support will enable commercial hosting of the project, fund the development and modification of various OpenSource software to accomodate the Yorùbá orthography.